Dẹ̀dẹ̀wùrẹ̀ Agége, Zindiq ati beebe lo ni awon apele ti awon osise tabi awon olulo lori ayelujara EsinIslam fun Habib Abdullahi ni Agege ti i se ikan ninu awon omo alufa agba ni Ile Yoruba ti opolopo ri gege bi oludojuti ati amunibuni eran ibiye ti o n fi orisirisi awon ede-aiyede ati ifenu da Esin Islam loju ru ni orile ede Naijiriya. E wo fanran fidio yii:
https://www.esinislam.com/YorubaZindiqVideosTV-c
Mo ri fanran fidio yi lori ayelujara EsinIslam ti o se alaiye awuyewuye lori iwuwa ati modaru Esin Habib Agege yi ni igba akoko lose ti o k'oja. Mo wo gbogbo awon ikan fidio naa patapata. Lehin eyi ni mo wa kan si awon baba-baba wa ti nwon je agba alufa paapaa julo ni Ilorin. Oro po ninu iwe kobo ni alaiye ti nwon se fun mi l'ori oro alufa Habib yii.
Sugbon ki n to lee menu baa oun gbogbo ti mo gbo nipa okunrin ti opolopo mo si Mudeer Al-Markaz yii, yio dara ki n se eda ona ti awon osise tabi awon olulo lori EsinIslam se alaiye eniti o n je Zindiq ninu Esin. E maa bami kalo...!
Ni akoko eyi ni bi nwon ti se ko akole afanran onifidio naa:
Habib Dedewure Lagege Is A Yoruba Zindiq* حبيب دَيْدَيْوُورَي من أغيغي هو زنديق* يوروبا
Ede Oyinbo ati Ede Larubawa nikan ni mo ri l'ori afanra yii ti nwon ti se alaiye eniti o n je Zindiq ati Dedewure latari eebu ti Habib n bu awon Sahabah (r.a.) ti o si n bu enu ete kan awon onimimo ti isaaju bi Imam Al-Bkhari ati beebe lo. Fun anfani awon ti nwon ko le be afanran yi wo, ma gbiyanju lati se itumo Ede Oyinbo naa si Ede Yoruba ni tikalara ti emi.
Eyi ni alaiye eniti o n je Zindiq ninu Esin Islam gege bi nwon ti se akosile re ni Ede Oyinbo:
*Zindiq in Islam, a zindiq is defined as someone who outwardly professes Islam but conceals disbelief and heresy, more severe than a hypocrite i.e. someone who outwardly acknowledges prophethood but in his heart maintains positions that oppose Islamic law or hold destructive opinions as hemiplegic ignorant Habib Dedewure of Agege does.
( copied from the page https://www.esinislam.com/YorubaZindiqVideosTV-c )
Alaiye eniti o n je Zindiq ninu Esin Islam gege bi nwon ti se akosile re ni Ede Larubawa:
الزنديق* في الإسلام هو من يظهر الإسلام ظاهريًا ولكنه يخفي الكفر والبدع، وهو أشد من المنافق أي من يقرّ بالنبوة ظاهريًّا ولكنه في قلبه يحتفظ بمواقف تعارض الشريعة الإسلامية أو يحمل آراء هدامة كما يفعل الجاهل المشلول حبيب دَيْدَيْوُورَي من أغيغي.
( copied from the page https://www.esinislam.com/YorubaZindiqVideosTV-c )
Ni ti temi, eyi ni bi emi ti gbo alaiye yi ye ni Ede Yoruba:
*Nínú ẹ̀sìn Islam, a túmọ̀ zindiq gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ń jẹ́wọ́ ẹ̀sìn Islam ní òde ara rẹ̀ ṣùgbọ́n tí ó ń fi àìnígbàgbọ́ àti àìgbàgbọ́ bo ara rẹ̀ mọ́lẹ̀, tí ó le ju Munafiq alágàbàgebè lọ, ìyẹn ni ẹnìkan tí ó ń jẹ́wọ́ jíjẹ́ Ojise Anabi (Muhammad) ní òde ara rẹ̀ ṣùgbọ́n tí ó ń di àwọn ipò tí ó lòdì sí òfin Islam mú tàbí tí ó ní àwọn èrò ìparun (si ẹ̀sìn Islam) gẹ́gẹ́ bí Habib Dedewure, amúkún òpè ènìyàn Agege, ṣe ń ṣe.
( translated as understood by myself )
Yio wumi lati menu ba dire ninu oun ti awon agbalagba alufa paapa julo ni Ilorin wi fun mi lori oro Habib yii ninu awon ti nwon ba baba re l'ogba. Sugbon ki n to le bere eleyii, yio wumi ki oluka ifiranse yii ba wa dasi oro yii latari ijiroro ni oju ewe yii. Enikeni lee ba wa dasi oro yii, paapaa julo pelu imo ati oye. Imo ni o ni Adini, e jowo ogbon ori ko. Ti enikeni ba si fe bawa dasi ijiroro yii, ki a ma bu awon olulo egbe wa lori aiyelujara yii tabi ki a so oro odi si awon osise EsinIslam ti nwon n fun wa ni anfaani ijiroro yii.
Eyin omo Yoruba, eyin Omo Kaaro-O-Jiire, Omoluabi ti o fi dori awa omo Ilorin e je ki a dasi oro yii pelu imo ati oye ti o peye...!
E se!!
Folashade (Sis.)