N Je Eyin Ranti Moo? Nigbati Buhari Omo Musa Sa Kuro Nibi Ayeye Igbeyawo Saidi Osupa: Lehin Ti Alfa Muri Bariga Fun Un N
Firanṣẹ: Àbámẹ́ta Oṣu kejila 20, 2025 8:23 am
N Je Eyin Ranti Moo? Nigbati Buhari Omo Musa Sa Kuro Nibi Ayeye Igbeyawo Saidi Osupa: Lehin Ti Alfa Muri Bariga Fun Un Ni Igbaju Olooyi
Aarin Osu kefa odun 2006 ni EsinIslam gbe Irohin Yoruba jade:
Lati Owo Lawal Taofeek Ariyo
Onirohin Yoruba yii ti oun naa je Musulumi se akosile bayii wipe:
Bawon alfaa atawon Mukadam ko ba tete wa ojutu si wahala to n waye lowolowo bayii laarin awon gbajumo alfa oniwaasi agbaye meji - Alhaji Buari omo Musa to fi iluu Ilorin nipinle kwara se ibugbe ati Alhaji Muritala Abdulkareem eni tawon eeyan tun mo si Alfa Muri Bariga, afaimo ki oro to n sele laarin awon ilumo-on-ka a oniwaasi mejeeji yii.
Ni satide ojo k i n n i o s u karun-un odun yii ni isele ti e fe ka nipa re yii sele nibii aye igbeyawo o b a o r i n - S a h e e d Osupa to waye l a g b e g b e Owode niluu Oyo Alaafin nipinle Oyo ni kete ti Alhaji Buari Omo Musa de sibi ayeye igbeyawo Alhaji Saheed Osupa ni o lo joko sinu ogba kan to wa legbe ibi ayeye ohun pelu awon omo eyin re tori ko si oruko re ninu iwe eto pe o maa wa pelu awon to se atokun eto lojo naa.
Sugbon eyinoreyin ni Alhaji Alawaye to se waasi nibii eto NIKKAI naa ni won so pe o bebe pe ki won fi oruko Alhaji Buari Omo Musa sori eto ki o ma dabii eni pe won ko ka a si tori won ni awon alfa to wa niluu Oyo ko gba ti Buari omo Musa tori won so pe igberaga ati asotan oro re ti po ju.
Koda adura ipari ni won fi si enu Buari omo Musa lojo naa. Gege bi Akede Oduduwa se gbo, Alfa Muri Bariga tawon eeyan mo si Alfa Saheed Osupa ni o koko lo ki Buari omo Musa nibi to joko si tori Alfa Muri Bariga ko ipa pataki lati pelu si aawo to wa laarin Alhaji Buari omo Musa ati Alhaji.
Kaasa! Alfulany ki edeaiyede to wa laarin won to yanju. Sugbon iyalenu loro naa je fun Alfa Muri Bariga tori bi aja ni Buari omo Musa se le e loju gbogbo ero boya ki o ma je pe eni ti o n se nnkan naa ni o tun n da agbo ru ni o je ki Alhaji Muri Bariga fun Buari omo Musa lesi.
Bi won se pe Alhaji Buari omo Musa pe ko wa se adua ipari eto tawon Musulumi n pe ni Robanna lo ba n pariwo sinu makirofoonu pe Alhaji Afesco lo mu oun mo Saheed Osupa, ko si eni to mu oun mo Saheed Osupa ati pe iro lawon yoku n pa.
Bakan naa ni Buari omo Musa tun fi adura ti won ni ko wa se sile ti o tun n fenuko nibi ti o ti n gbiyanju lati mu ori Alhaji Kollington Ayinla (KEBE 1) wu.
Ani Buari omo Musa so pe gbogbo awon to sunmo Kebe-NKwara ninu awon olorin fuji ni ara won n se kebekebe ; bee si ni aisan to n se Alhaji Barrister ati Alhaji Wasiu Ayinde ni won so pe Alhaji Buari omo Musa ti fi igba kan so pe oun loun wa nidii oro won bi o tile je pe o ti so pe oun ko mo nnkan kan nipa aisan to n se won koda nibi ayeye kan ti gbajumo sorosoro to fi iluu Ibadan se ibugbe, Alhaji Kola Olootu se laipe yii ni won ti so pe buari omo Musa tun s o pe oun loun wa n i d i i o r o Alhaji Barrister loju gbogbo ero sugbon to je pe ni se lo pada pe Alhaji Kola Olootu lori foonu lati be e pe ki o ba oun yo o kuro n i n u f i d i o waasi, ohun tori oun ko mo ohun to kolu oun lasiko toun n so oro naa.
Bi Alhaji Buari omo Musa se fi makirofoonu sile ti o fe maa lo ni Alhaji Afesco pe e lati ba a soro sugbon nise ni Alfa Muri Bariga lo anfaani ohun lati yeye Buari omo Musa nita gbangba nipa bi o se ko igbaju olooyi fun-un ti oun atawon omo eyin re si fi oro naa se "-ori-yo-o-" tori nise ni won ko duro mu lawani won to jabo sile.
"Mo ti lo alomo" ni won so pe Buari omo Musa so di orin titi ti o fi feyin rin kuro nibi isele ohun ti o si n leri oogun si Alfa Muri B a r i g a . A k e d e Oduduwa gbiyanju lati wadi i isele y i i a si p e Alf a Mur i Bar iga lor i foonu, alaye ti o se fun wa nipe bi ko ba je pe ti awon agbaagba Alfa bii Akeugba Gold, Alhaji Alawaye atawon miran to wa nibi ayeye ohun ni nise loun ko ba lu Buari omo Musa daku lojo naa tori oun ko mo ese ti oun se e; sugbon to je pe nise lo fe maa fi oun gba irawo loju gbogbo eniyan.
Alfa Muri Bariga salaye pe ile keu kan naa loun ati Buari omo Musa jo lo yato si pe awon jo je omo bibi iluu Ilorin bee si ni ko si ohun rere ti Buari omo Musa ti gbe se laye ti oun naa ko gbe se ki lo wa de to je pe iwa ilara ko je ki Buari omo Musa o gbadun.
Alfa Muri Bariga tun so pe ko si ode ti won n pe Buari omo Musa si niluu Ilorin ju ode "Olobinrin de" lo tori iwa janduku ati oro alufansa to wa lenu e bee si ni moto alajapa ni baba re n wa niluu ilorin tele, sugbon Buari omo Musa so pe idile oun ni ise alfa ti bere koda rekoodu kan n bo lona ti yoo salaye bi aisan opolo se da meji ninu awon egbon Buari. omo Musa gunle niluu Ilorin atawon asiri mi-in tawon eeyan ko mo nipa agboole re niluu Ilorin. Abalajo ti buari omo Musa fi maa n so pe ko seni ti oun ko le ba ja nitori owo.